Skentele Skontolo

Album: Africano: The Mother of Groove Year: 2005 Afrobeats Checked
Select any line to read notes
INTRO
INTRO
Kò sí fashion kan tó ju ti(w)a lọ
There’s no fashion better than ours
Ìró àti bùbá yẹn pẹ̀lú gèlè skontolo.
The wrapper with the blouse, topped with the gèlè skontolo.
STANZA
STANZA
Gèlè ò dùn bíi ká mọ̀ọ́ wé
The gèlè isn’t as sweet as knowing how to adorn it.
Ká mọ̀ọ́ wé kò dàbíi kó yẹ ni. (x2)
And to adorn it isn’t as good as making it fit. (x2)
Èyí yẹ ẹ́ ò, baba ta ló sọ pé kò yẹ ẹ́?
This one fits you, whose father says otherwise?
Àwọn dà?
Where are they?
Baba ta ló sọ pé kò yẹ ẹ́?
whose father says it doesn’t fit you?
Kí kẹ́kẹ́ pa (kó pa) mọ́ wọn lẹ́nu
May silence fall (may it fall) on their mouths
Kẹ́kẹ́-tí-kẹ́ pa mọ́ baba wọn lẹ́nu.
May silence fall and lock their fathers’ mouths.
Kí kẹ́kẹ́ pa sẹ́ (kó pa mọ́ wọn lẹ́nu sẹ́!)
I say may silence fall (and fall on their mouths)
Kẹ́kẹ́-tí-kẹ́ pa mọ́ baba wọn lẹ́nu.
May silence fall and lock their fathers’ mouths.
Ọ̀rọ̀ hunrunhunrun, inú ẹlẹ́dẹ́ ló mi gbé
Words of murmuring remain locked in the pig’s stomach
Tó bá ṣ'ojú ló ń dùn wọ́n, ká gba jígí fún wọn.
So if it’s their eyes that are defective, we may buy them a mirror!
BRIDGE:
BRIDGE:
Ṣé (ní)torí mi lẹ lọ gẹ gèlè skẹntẹlẹ (x2)
Is it because of me that you adorned your gèlè skentele? (x2)
Àbí torí wọn lẹ gẹ gèlè skẹntẹlẹ
Or is it because of them that you set your gèlè skentele?
Tó bá ṣe (ní)torí mi lẹ gẹ (gèlè) skẹntẹlẹ
If it’s because of me that you set your gèlè skentele
Èmi náà á gẹ fìlà mi skontolo!
I, too, will adorn my cap skontolo!
CHORUS:
CHORUS:
Onígèlè yìí (Skẹntẹlẹ)
Oh, this gèlè-adorned woman (Skentele)
Ẹ jọ̀ọ́ mà (Skontolo) (x3)
Oh, do be merciful! (Skontolo) (x3)
Kílódé?
Oh why??
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
O ti lọ wà jù baby
You’re so pretty, baby
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Ẹ yáa má fìyẹn já wa lójú
Please don’t get us too jealous of it!
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Èyí wà nílẹ̀, ẹ dẹ̀ ní kò sí nǹkankan.
You have all of this, and you’re playing coy!
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Kílódé?
Oh why?
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Why o, mama?
Why oh, mama?
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Mi ò mà mà r'ẹ̀yìn ma!
My view of the (car) rear is blocked, ma!
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bá mi sún síbí
Please, can you move to one side, please?
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Ẹ jẹ́ kí n rí'wájú.
So I can see the front.
Eh Onígèlè yìí (Skẹntẹlẹ)
Eh this gèlè-adorned woman (Skẹntẹlẹ)
Ẹ jọ̀ọ́ mà (Skontolo) (x3)
Oh, do be kind (Skontolo) (x3)
Kílódé?
Oh why?
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Àréè! Ẹ má mà jẹ́ ó jábọ́!
Oh no! Do not let it fall!
Ó mà ti fẹ́ tú lẹ́yìn kẹ̀!
It’s almost unraveling in the back!
Àbí kí n shock ẹ̀ lẹ́yìn níbi?
Should I help you support it here?
Tẹẹ̀ bá tètè shock ẹ̀ á jábọ́!
If you don’t support it quick, it might fall!
Load yìí ò wa pọ̀jù aunty!
Isn’t this load too much, aunty!
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Tóo bá ṣèèṣì yíi sẹ́yìn á túká!
One little mistake to the back, and it all disintegrates!
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Why o mama?
Why oh mama?
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
Ṣóo fẹ́ yí mi lórí ni?
Are you trying to turn my head inside-out?
O ti lọ wà jù baby.
You’re so fine, baby.
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
(Skẹntẹ́lẹ́ Skontolo)
This one tell me say nothing-nothing dey.
This one told me that it’s nothing much.
Ah, onígèlè yìí (Skẹntẹlẹ)
Ah, this gèlè-adorned woman (Skẹntẹlẹ)
Ẹ jọ̀ọ́ mà (Skontolo).
Oh, please ma, be kind (Skontolo).
BASS GUITAR AND DRUMS
Kọjúsọ́kọ
Huband-facing!
Umbrella
Umbrella!
Labalábá
Butterfly!
Ice cream!
Ice cream!
Ceiling fan.
Ceiling fan.
Lukumon
Lukumon
National Theatre.
National Theatre.
Ẹ wo gèlè gẹngẹ lórí ajígbọ́tọkọ
Look at the adorned gèlè on the head of the husband-pleasing woman
(Human diesel!)
(Human diesel!)
Ẹ wo gèlè gẹngẹ lórí ajígbọ́tọkọ
Look at the adorned gèlè on the head of the husband-pleasing woman
Ayé ni n ó jẹ n ò ní j'ìyà
I will enjoy my life; I’m not built for suffering!
Ẹ wo gèlè gẹngẹ lórí ajígbọ́tọkọ.
Look at the adorned gèlè on the head of the husband-pleasing woman
(Satellite!)
(Satellite!)
Ẹ wo gèlè gẹngẹ lórí ajígbọ́tọkọ.
Look at the adorned gèlè on the head of the husband-pleasing woman
(Boys-follow-me!)
(Boys-follow-me!)
Ẹ wo gèlè gẹngẹ lórí ajígbọ́tọkọ.
Look at the adorned gèlè on the head of the husband-pleasing woman
(Overload leléyìí o).
(This one is an overload!).
Tẹ́ẹ bá gẹ gèlè skẹntẹlẹ
If you set your gèlè skentele
Màá gẹ fìlà skontolo (x3)
I’ll also adorn my own cap skontolo (x3)
Fẹ́m! (Fẹ̀m!)
Fẹ́m! (Fẹ̀m!)
Kọ́n panu wọn mọ́ ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀!
This means “may they all be quiet!”
Ṣé baby yẹn wọ̀wọ́?
Is that lady ugly?
Kò wọ̀wọ́! (x4)
She’s not ugly! (x4)
Wọ̀wọ́ girls don finish for Nigeria!
There are no more ugly girls in Nigeria!
EGO:
EGO:
Ẹ má tórí mi (x2) rèé jàjàkú o!
Don’t because of me (x2) go fight to the death!
(Ìwọ, lẹ́nuẹ!)
(You! Too heavy for your mouth!)
Ẹ má tórí wa, Ẹ má tórí wa
Don’t because of us, don’t because of us
Ẹ má tórí wa rèé jàjàkú o!
Don’t because of us go fight to the death!
Ẹni gèlè mi bá w'orí ẹ̀ ló mí a wée (x2)
The one whose head fits my gèlè is the one that will sport it (x2)
Ẹ má tórí mi, Ẹ má tórí wa
Don’t because of me, don’t because of us
Ẹ má tórí mi rèé jàjàkú o!
Don’t because of me go fight to the death!
(Iwọ́!)
(Oh you!)
Gèlè ò dùn bíi ká mọ̀ọ́ wé
The gèlè isn’t as sweet as knowing how to adorn it.
Ká mọ̀ọ́ wé kò dàbíi kó yẹ ni. (x2)
And to adorn it isn’t as good as making it fit. (x2)
Èyí yẹ ẹ́ ò, baba ta ló sọ pé kò yẹ ẹ́?
This one fits you, whose father says otherwise?
Baba ta ló sọ pé kò yẹ ẹ́?
Whose father says it doesn’t fit you?
Kí kẹ́kẹ́ pa (kó pa) mọ́ wọn lẹ́nu.
May silence descend on their mouths.
Ṣé (ní)torí wa lẹ lọ gẹ gèlè skẹntẹlẹ
Is it because of me that you adorned your gèlè skentele?
Tó bá ṣe (ní)torí mi lẹ lọ gẹ gèlè skẹntẹlẹ
If it’s because of me that you set your gèlè skentele
Èmi náà á gẹ fìlà mi skontolo!
I, too, will adorn my cap skontolo!
Eh, ṣé (ní)torí wa lẹ lọ gẹ gèlè skẹntẹlẹ
Eh, is it because of us that you adorned your gèlè skentele?
Tó bá ṣe (ní)torí mi lẹ lọ gẹ gèlè skẹntẹlẹ
If it’s because of me that you set your gèlè skentele
Èmi náà á gẹ fìlà mi skontolo!
I, too, will adorn my cap skontolo!
Onígèlè yìí (Skẹntẹlẹ)
You this gèlè-adorned woman (Skẹntẹlẹ)
Ẹ jọ̀ọ́ mà (Skontolo)...
Oh, do be kind (Skontolo) …
Edit in CMS